Access Bank

Access Bank
Access Bank PLC
TypePublic
Founded1989
Headquarters14/15, Prince Alaba Abiodun Oniru Road, Victoria Island, Lagos, Lagos State, Nigeria
Key peopleHerbert Wigwe
Dr. Ajoritsedere Awosika, Chairperson
Group Managing Director
Chief Executive Officer
IndustryBanking
ProductsLoans, Credit Cards, Savings, Investments, Mortgages
Revenue US$1,419 million (NGN:514 billion) (Sept 2019)
Total assetsUS $25.5 billion (NGN: 10.055 trillion) (2021)
Employees28,121
Websiteaccessbankplc.com

 

Access Bank plc, tí a mọ̀ sí Access Bank, jẹ́ ilé-ìfowópamọ́ gbogboogbò ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà; ó sì jẹ́ ohun-ìní Access Bank Group . Ó ní ìwé-àṣẹ nípasẹ̀ Central Bank of Nigeria, olùṣàkóso ilé-ìfowópamọ́ orílẹ̀-èdè. [1]

Ní àkọ́kọ́, wọ́n jẹ́ báńkì ilé-iṣẹ́ kan; ní ọdún 2012, wọ́n gbòòrò sí báńkì ti ara-ẹni àti ilé-ìfowópamọ́ ìṣòwò. Access Bank àti Diamond Bank dàpọ̀ ní Ọjọ́ kìn-ín-ní, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2019. Ní ìparí ìdàpọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ìfowópamọ́ ti Diamond, Access Bank ṣe àfihàn ààmì ìdánimọ̀ tuntun rẹ̀, èyí tí ń ṣe àfihàn ìbẹ̀rẹ̀ ti ilé-ìfowópamọ́ tuntun ńlá kan. Ilé-ìfowópamọ́ yìí gba àwọn òṣìṣẹ́ tó lé ní 28, 000 ní ọdún 2021.[2]

Àwòrán ìdánimọ̀ Access Bank

Lẹ́yìn ìṣọpọ̀ yìí, Access Bank plc di báǹkì tí ó tóbi jùlọ ní Áfíríkà lágbọn ti oníbàárà, pẹ̀lú àwọn oníbàárà tó ju mílíọ̀nù méjìlélógójì lọ, àti báńkì tí ó tó tóbi jùlọ ní Nàìjíríà lágbọn ti dúkíà.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2021, Access Bank kéde pé ó ti ṣe ìdánimọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà tuntun mẹ́jọ fún ìfẹ̀lójú tó lọ́ọ̀rìn, pẹ̀lú èróńgbà láti je àǹfàní láti inú àdéhùn ìṣòwò ọ̀fẹ́ jákèjádò kọ́ńtìnẹ́ẹtì kan. Awọn ìlú tó jẹ́ ọjà àfojúsùn wọn ni Morocco, Algeria, Egypt, Côte d'Ivoire, Senegal, Angola, Namibia àti Etiopia, èyítí yóò ṣe ìfẹ̀lójú mímọ̀-lágbàáyé báńkì náà sí àwọn orílẹ̀-èdè méjìdínlógún. Access Bank ni a nírètí láti ṣètò àwọn ọ́fíìsì sí àwọn orílẹ̀-èdè, ṣe alábàáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-ìfowópamọ́ tó wà, àti kí ó lo àwọn ẹ̀rọ agbagbe rẹ̀ láti ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn oníbàárà.

Àwọn ìtọ́kasí

  1. . Abuja.  Missing or empty |title= (help);
  2. "Our History". Access Bank Group. Retrieved 1 November 2021. 

Content Disclaimer

Informasi ini disarikan dari Wikipedia dan disajikan kembali untuk tujuan edukasi. Konten tersedia di bawah lisensi CC BY-SA 3.0. Kami tidak bertanggung jawab atas ketidakakuratan data yang bersumber dari kontribusi publik tersebut.

  1. The information displayed on this website is sourced in part or in whole from Wikipedia and has been adapted for the purpose of restating it. We strive to provide accurate and relevant information, however:
  2. There is no guarantee of absolute accuracy. Wikipedia is an open, collaborative project that can be edited by anyone, so information is subject to change.
  3. It is not intended to constitute professional advice. The content displayed is for informational and educational purposes only. For important decisions (e.g., medical, legal, or financial), please consult a professional.
  4. Content copyright. Wikipedia is licensed under the Creative Commons Attribution-ShareAlike License (CC BY-SA). This means that content may be reused with appropriate attribution and shared under a similar license.
  5. Responsible use. Any risk arising from the use of information from this website is entirely the responsibility of the user.