Boxing

A woman's boxing match in Uruguay in 2008

Ẹ̀ṣẹ́ kíkàn ni o jẹ́ eré ìdárayá oníjà àwọn tí ́ò gbajùmọ̀ lọ́dọ̀ àwọn Gẹ̀ẹ́sì.[1] ti o ma n waye ni inu oju agbo onigun mẹrin ti a pese fun un. Ẹ̀ṣẹ́ kíkàn ni o ma n ni awọn oludije meji ti wọn yoo ma koju ara wọn nipa jiju tabi kikan ara wọn ni ẹṣẹ fun awọn asiko perete ti wọn ba ya silẹ fun naa ni ọwọ kọọkan. Awọn abẹṣẹ ku bi òjò ma n wọn awọn nkan idaabobo bii: ìbọ̀wọ́, ibo-eyín ati bẹẹ bẹẹ lọ lati fi daabo bo ara wọn ṣaaju ki ija ẹṣẹ kikan to bẹrẹ loju agbo.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé eré ìdárayá àwọn Gẹ̀ẹ́sì ni eré yí bí a ti sọ, kò fẹ́ẹ̀ sí ibi tí wọn kò ti kí ń ṣe eré ìdárayá yìí ní gbogo àgbáyé lónìí. Gbogbo ibi kíbi tí àwọn mejì bá ti ń jà tí wọ́n sì ń sọ ẹ̀ṣẹ́ lu ara wọn, yálà wọ́n fi ń ṣeré ni tàbí wọ́n ń ja ìjà tòótọ́ ni wọ́n ti ma ń pèé ní ẹ̀ṣẹ́ kikàn (boxing). Lọ́pọ̀ ìgbà, kìí ṣe ẹ̀ṣẹ́ nìkan ni wọ́n ma ń lò láti fi ja ìjà yí, wọ́n lè lo ìpá jíjù, ìgúnpá, orúnkún, tàbí ìgbò kikàn, èyí dá lórí òfin tí wọ́n bá fi de àwọn oníjà méjèèjì náà. Àwọn eré ìdárayá mìíràn tí wọ́n tún ń lo gbogbo ara láti fi jà bẹ́ẹ̀ ni: bare-knuckle boxing, kickboxing, Muay Thai, Lethwei, savate, àti sanda.[2][3] Àmọ́ ṣá, ọgbọ́n ẹ̀ṣẹ́ kíkàn ni wọ́n ti ń ṣàmúlò nínú àwọn eré oníjà mìíràn jákè-jádò àgbáyé báyìí.

Nínù ìtàn ọmọnìyàn, ó fi hàn wípé ènìyàn ti ń lo ẹ̀ṣẹ́ láti fi bá ara wọn jà lọ́jọ́ tò ti pẹ́. Àmọ́ ìgbà àti àsìkò tí ẹ̀ṣẹ́ kíkàn di eré ìdárayá ni ẹnìkẹ́ni kò mọ̀.[4] Àwọn àpilẹ̀kọ kan sọ wípé ẹ̀ṣẹ kíkàn ti bẹ̀rẹ̀ ṣáájú kí wọ̀n tó bẹ̀rẹ̀ ìtàn kíkọ ní ǹkàn bíi 6th millennium BC ní ibi tí a mọ̀ sì Ethiopia lónìí. Àwọn kan gbàgbọ́ wípé àwọn ará ilẹ̀ Egyptians ni wọ́n ya wọ ilẹ̀ Nubia nígbà kan tí wọ́n sì kọ́ nípa ẹ̀ṣẹ́ kíkàn lọ́dọ̀ àwọn ará ilẹ̀ Ethopia nígbà náà, ṣáájú kí wọ́n tó ma fi ṣe eré ìdárayá ní ilẹ̀ Egypt. Láti ibẹ̀ ni eré ìdárayá ẹ̀ṣẹ́ kíkàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ń tàn káàkiri àgbáyé.[5]

Àwòrán tí ó ṣàfihàn ẹ̀ṣẹ́ kíkàn gan an ni ó jẹyọ láti ilẹ̀ Egypt àti ilẹ̀ Sumer ní ǹkan bíi mílẹ́níà kẹta (3rd millennium)[6] tí wọ́n sì rí àwọn àwòrán yí ní ibi tí àwọn ènìyàn Sumeri ń ya àwòrán wọ́n sí ní àárín mìlẹ́níùm kejì sí ìkẹta BC .[7][8][9][10] Òfin tí ó de ẹ̀ṣẹ́ kíkan bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ Greece atijọ, nígbà tí wọ́n da ẹ̀ṣẹ́ kíkàn pọ̀ mọ́ ìkan lára àwọn eré ìdárayá ti Olympic games ní 688 BC.[7] Eré ẹ̀ṣẹ́ kíkàn ni ó di àpèwáwò láti ìgbà tí wọ́n ti ń gbé owó ribribi lé e ní àárín ọ̀rùndún kẹrìndínlógún sí ìkejìdínlógún (16th - 18th-centuries), pàá pàá jùlọ ní ilẹ̀ Britain. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ń lo òfin Marquess of Queensberry Rules nínú eré ẹ̀ṣẹ́ kíkàn ní ọdún 1867.

Alàgata tí ó wà láàrín àwọn òǹdíje ẹ̀ṣẹ́ kíkàn méjì ni wọ́n ń pè ní (rẹfurí) [11] òǹdiwọ̀n ìgbà tí àwọn abẹ̀ṣẹ́kù méjèèjì yóò jà ni ó ma jẹ́ ìṣẹ́jú kan sí mẹ́ta làárín ìpele mẹ́ta. Wọ́n lè kéde olùborí láàrín àwọn méjèèjì ṣáájú kí ìpele kan tó kẹ́sẹjárí nígbà tí kò bá lè tẹ̀síwájú mọ́, tàbí tí wọ́n bá yọ olùdíje kan kúrò, tàbí tí wọ́n bá na olùdíje kan sọwọ́ sìlẹ̀ pé òun kò jà mọ́. Nígbà tí ìjà bá ti parí tí ẹnìkan kò sọwọ́ sílẹ̀ fún ẹnìkejì, tàbí tí àwọn méjèèjì jọ ta ọ̀mì tí àwọn adájọ́ sì ní láti kéde ẹnìkan bí olúborí, àwọn adájọ́ yóò lo àwọn ọgbọ́n ìmọ̀ ẹ̀rọ láti fi yan ẹni tí ó jáwé olúborí nínú ìdíje náà.

Àwọn ìtọ́kasí

  1. Boxing is a martial art:
  2. Green, Thomas A. (11 June 2010). Martial Arts of the World: An Encyclopedia of History and Innovation. 2. Bloomsbury Academic. ISBN 978-1-59884-243-2. https://books.google.com/books?id=FaTfuuIlmqcC. 
  3. Acevedo, William; Cheung, Mei (2011). "Una visión histórica de las artes marciales mixtas en China". Revista de Artes Marciales Asiáticas 6 (2): 29–44. doi:10.18002/rama.v6i2.6. Archived from the original on 2025-12-21. https://web.archive.org/web/20251221141933/https://revpubli.unileon.es/ojs/index.php/artesmarciales/article/view/6. Retrieved 2026-03-19. 
  4. Gould, William B.; Greely, Henry T. (2004). Symposium: Sports and the Law. Stanford Law School. p. 9. https://books.google.com/books?id=9DxDAQAAIAAJ. 
  5. Blewett, Bert (2002). The A-Z of world boxing: an authoritative and entertaining compendium of the fight game from its origins to the present day. Parkwest, N.Y.: Robson Books. p. 296. ISBN 978-1-86105-294-0. https://archive.org/details/azofworldboxinga0000blew. 
  6. Boxing equipment and history - Olympics
  7. 7.0 7.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named EncyclopaediaBritannicaEntry
  8. Murray, Steven Ross (2010). "Boxing Gloves of the Ancient World". ejmas.com. 
  9. Mohamed, Fawziah Abdullah (31 December 2020). "Early Evidence of Boxing in Ancient Egypt and Mesopotamia: A Comparative Study". Shedet 7 (7): 74–86. doi:10.21608/shedet.2020.137664. https://shedet.journals.ekb.eg/article_137664.html. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  10. Lee-Barron, James R. (2012). "The Martial Science of Boxing and its Contribution to Military Close Combat". Ido Movement for Culture: Journal of Martial Arts Anthropology 12 (4): 20–25. Archived from the original on 20 May 2022. https://web.archive.org/web/20220520101900/https://bazhum.muzhp.pl/media/files/Ido_Movement_for_Culture_journal_of_martial_arts_anthropology_theory_of_culture_psychophysical_culture_cultural_tourism_anthropology_of_martial_arts_combat_sports/Ido_Movement_for_Culture_journal_of_martial_arts_anthropology_theory_of_culture_psychophysical_culture_cultural_tourism_anthropology_of_martial_arts_combat_sports-r2012-t12-n4/Ido_Movement_for_Culture_journal_of_martial_arts_anthropology_theory_of_culture_psychophysical_culture_cultural_tourism_anthropology_of_martial_arts_combat_sports-r2012-t12-n4-s20-25/Ido_Movement_for_Culture_journal_of_martial_arts_anthropology_theory_of_culture_psychophysical_culture_cultural_tourism_anthropology_of_martial_arts_combat_sports-r2012-t12-n4-s20-25.pdf. 
  11. Australia, Boxing. "The Neutral Corner". www.boxing.org.au (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-01-30. 

Content Disclaimer

Informasi ini disarikan dari Wikipedia dan disajikan kembali untuk tujuan edukasi. Konten tersedia di bawah lisensi CC BY-SA 3.0. Kami tidak bertanggung jawab atas ketidakakuratan data yang bersumber dari kontribusi publik tersebut.

  1. The information displayed on this website is sourced in part or in whole from Wikipedia and has been adapted for the purpose of restating it. We strive to provide accurate and relevant information, however:
  2. There is no guarantee of absolute accuracy. Wikipedia is an open, collaborative project that can be edited by anyone, so information is subject to change.
  3. It is not intended to constitute professional advice. The content displayed is for informational and educational purposes only. For important decisions (e.g., medical, legal, or financial), please consult a professional.
  4. Content copyright. Wikipedia is licensed under the Creative Commons Attribution-ShareAlike License (CC BY-SA). This means that content may be reused with appropriate attribution and shared under a similar license.
  5. Responsible use. Any risk arising from the use of information from this website is entirely the responsibility of the user.