Goggo Addi
| Goggo Addi | |
|---|---|
| Ọjọ́ ìbí | 1911 |
| Ọjọ́ aláìsí | 1999 |
| Iṣẹ́ | Òpìtàn |
| Ọmọ orílẹ̀-èdè | Ọmọ orílè-èdè Cameroon |
Goggo Addi ( c. 1911 – Oṣù kọkànlá ọdún 1999) jẹ́ akọ̀tàn ọmọ orílè-èdè Cameroo tí ó ń pè dè pẹ̀lú èdè Fula . Ó ṣe àgbékalè àwọn ìtàn níbi àkójọ pọ̀ oríṣìíríṣìí ní orílẹ̀-èdè náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, láti ọdún 1985 sí 1989 ó gbà láti jẹ́ kí olùwádìí Ursula Baumgardt gba àwọn ìtàn rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì kọ wọ́n sílẹ̀, èyí sì ṣe àfikún pàtàkì àti igbe lárugẹ sí àṣà ìtàn sísọ ní ìwọ oòrùn Áfíríkà.[1]
Ìtàn ìgbésí ayé ìbéèrè
A bí Goggo Addi ní ọdún 1911 tàbí bóyá ọdún 1912 ní Bibemi, ní àríwá orílè-èdè Cameroon, ní àkókò ìgbóguntì àwọn ará Akonilede ará orílè-èdè Germany àti ìdènà sí ìkọlù yìí.[2] Bàbá rẹ̀ jẹ́ ọlọ́rọ̀ oníṣòwò Fulani Mùsùlùmí, tí ó ní ìyàwó mẹ́rin. Ní ọdún 1914, ìdílé rẹ̀ kúrò ní Bibemi lọ sí ìlú Garoua, níbi tí baba rẹ̀ kú sí ní ọdún méjì lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n kó dé ìlú náà. Ní ọdún náà, àwọn ará Faransé gba ìlú náà lọ́wọ́ àwọn ará Germany. Addi dúró níbẹ̀ pẹ̀lú ìyá rẹ̀, tí ó tún fẹ́ ọkọ, àti àwọn àbúrò rẹ̀, ṣùgbọ́n ipò ọ̀rọ̀ ajé wọ́n tí dénú kole kó sí ọ̀rọ̀ bí tí tẹ́lẹ̀ mọ́.[3][4] Wọ́n fipá mú Addi láti ṣe ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n ó fi ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ sílẹ̀, ó sì fẹ́ ọmọ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ baba rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ó di ẹni tí ó ń hùwà ìkà sí i, ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ moodibbo kan, olórí ẹ̀sìn Islam, láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ó padà sí ìlú ìbí rẹ̀ ní Bibemi, níbi tí ó ti di olókìkí gẹ́gẹ́ bí akọ̀tàn, tí ó ń ṣe àpèjọ àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ní àgbègbè náà. Nítorí pé ó ní òmìnira, Addi tún fẹ́ ọkọ ní ìgbà mẹ́fà sí i. Sugbọn kò bí ọmọ kánkán, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó bí àbikù méjì.[3] Ní ọdún 1985, àwọn ẹbí rẹ̀ kan sí oníṣẹ́ ìwádìí ìjìnlè Ursula Baumgardt, ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní ileeko Institut national des langues et civilizations orientales àti ọmọ ẹgbẹ́ iṣẹ́ ìwádìí kan lórí èdè àti àṣà ìbílẹ̀ Áfíríkà ní French National Centre for Scientific Research . Àwọn obìnrin méjèèjì ṣiṣẹ́ papọ̀ títí di ọdún 1989 láti gba àwọn ìtàn Addi sílẹ̀ àti láti kọ wọ́n sílẹ̀, pẹ̀lú Baumgardt tí ó mọ ń lọ sí àwọn ìṣeré alẹ́ rẹ̀ àti láti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. Wọ́n ń jó ń ṣe ìbáṣepọ̀, wọ́n tún pàdé ní ọdún 1993 àti 1995. Addi kú sí ìlú Garoua, níbi tí ó ti padà sí láti gbé ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní oṣù kọkànlá ọdún 1999.[4][5][3]
Àwọn Ìtọ́kasí
- ↑ "Discovering Languages:The 'ABCs' of the Fula Language". Canadian Association of Second Languages. 6 November 2024.
- ↑ L'islam politique au sud du Sahara : identités, discours et enjeux. Muriel Gomez-Perez, Laboratoire Sociétés en développement : études transdisciplinaires, Impr. Laballery). Paris: Éd. Karthala. 2005. ISBN 2-84586-615-1. OCLC 470422489.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 Baumgardt, Ursula (2000). Une conteuse peule et son répertoire : Goggo Addi de Garoua, Cameroun : textes et analyses. Goggo Addi. Paris: Karthala. ISBN 2-84586-104-4. OCLC 45647204.
- ↑ 4.0 4.1 Baumgardt, Ursula (2013). "Goggo Addi [ Bibémi V.1911-Garoua 1999]". Le dictionnaire universel des créatrices. Béatrice Didier, Antoinette Fouque, Mireille Calle-Gruber. Paris: Des femmes-A. Fouque. pp. 1765–1766. ISBN 978-2-7210-0651-6. OCLC 1033526247.
- ↑ Derive, Jean (2001-01-01). "Baumgardt, Ursula. – Une conteuse peule et son répertoire. Goggo Addi de Garoua, Cameroun. Paris, Karthala, 2000, 548 p." (in fr). Cahiers d'études africaines 41 (163–164). doi:10.4000/etudesafricaines.127. ISSN 0008-0055.
Content Disclaimer
Informasi ini disarikan dari Wikipedia dan disajikan kembali untuk tujuan edukasi. Konten tersedia di bawah lisensi CC BY-SA 3.0. Kami tidak bertanggung jawab atas ketidakakuratan data yang bersumber dari kontribusi publik tersebut.
- The information displayed on this website is sourced in part or in whole from Wikipedia and has been adapted for the purpose of restating it. We strive to provide accurate and relevant information, however:
- There is no guarantee of absolute accuracy. Wikipedia is an open, collaborative project that can be edited by anyone, so information is subject to change.
- It is not intended to constitute professional advice. The content displayed is for informational and educational purposes only. For important decisions (e.g., medical, legal, or financial), please consult a professional.
- Content copyright. Wikipedia is licensed under the Creative Commons Attribution-ShareAlike License (CC BY-SA). This means that content may be reused with appropriate attribution and shared under a similar license.
- Responsible use. Any risk arising from the use of information from this website is entirely the responsibility of the user.