Iroko

Taxonomy not available for Milicia; please create it automated assistant
Iroko
Milicia excelsa, ní Uganda
Ìṣètò onísáyẹ́nsì [ e ]
Àwọn ẹ̀yà

Milicia excelsa
Milicia regia

Ìrókò jẹ́ igi ńlá tó le gidi (hardwood) láti etíkun ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà olóoru tí ó lè gbé títí di ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọdún.[1] Èyí ni orúkọ gbogbogbò fún ìdílé igi Milicia, nínú èyí tí a ti mọ ẹ̀yà méjì tí wọ́n pẹkí pọ̀ pẹ́kípẹ́kí: Milicia excelsa àti Milicia regia.[2]

Orúkọ ìdílé Milicia wà fún ọlá Milici (ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún àti ogún), alákòóso kan ní Ìlà-oòrùn Áfíríkà ti àwọn Pọ́túgà (ní orílẹ̀-èdè Mozambique lóde òní) ẹni tí ó ṣàtìlẹ́yìn iṣẹ́ ònkọ̀wé ìdílé igi náà, Thomas Robertson Sim.[3] Wọ́n kọ́kọ́ ṣàpèjúwe rẹ̀ tí wọ́n sì gbé e jáde nínú ìwé Forest Fl. Port. E. Afr. ní ojúewé 97 ní ọdún 1909.[4]

Àwọn Yorùbá mọ igi yìí sí ìrókò, logo tàbí loko, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ó ní agbára ìwòsàn.[5] Àwọn Ìgbò mọ Ìrókò sí igi ọjị.[6] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn igi tí wọ́n sábà máa ń pè ní African teak (teak ti Áfíríkà),[7] bótilẹ̀jẹ́pé kò ní ìbátan kankan pẹ̀lú ìdílé igi teak. Àwọ̀ igi náà máa ń jẹ́ òféèfèé (yellow) níbẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n yóò yí padà sí àwọ̀ ilẹ̀ tó dúdú púpọ̀ (copper brown) bí àkókò ti ń lọ.

Igi Ìrókò

Àwọn Orúkọ ní Èdè Mìíràn

Àwọn Ẹ̀yà

Wọ́n ń rí igi ìrókò púpọ̀ jùlọ láti ara Milicia excelsa. Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé nípa igi yìí, orúkọ àwọn igi tó ń pèsè rẹ̀ ni wọ́n pè ní Chlorophora excelsa (tí í ṣe Milicia excelsa) àti Chlorophora regia (tí í ṣe Milicia regia).[13][14]


Milicia excelsa wà lákọsílẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ewéko 'tó fẹ́rẹ̀ parun' lórí àtòjọ IUCN Red List.[15]

Àwọn ẹ̀yà méjèèjì yìí jẹ́ igi tí ó ní akọ àti abo lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ (dioecious), èyí tí ìtànná akọ àti abo rẹ̀ máa ń wà lára igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.[16]

Àwọn Ìwúlò Rẹ̀

Àwòrán igi Ìrókò tí a ti gé

Wọ́n ń lo pákó rẹ̀ fún onírúurú nǹkan nínú ilé àti lóde[17] títí kan ṣíṣe ọkọ̀ ojú-omi, pákó ìlẹ̀ ilé, ohun-ọ̀ṣọ́ ilé (furniture) àti àwọn gétì ìta. Láti ìparí àwọn ọdún 1990, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó gẹ́gẹ́ bí ara ohun èlò orin txalaparta ti Basque, tí a fi pákó igi ṣe, nítorí ìró dídùn rẹ̀.[18] Ìrókò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn pákó tí wọ́n ń lò fún ṣíṣe ìlù ìbílẹ̀ djembe.

Igi ìrókò ni pákó tí wọ́n yàn fún àwọn ìjókòó (pew) inú ṣọ́ọ̀ṣì Our Lady of Peace Basilica.[19]

Ó jẹ́ igi tí ó pẹ́ títí gidi;[20] ìrókò kò nílò ìtọ́jú pẹ̀lú epo tàbí omi pákó nígbàgbogbo fún lílò níta, bótilẹ̀jẹ́pé ó ṣòro púpọ̀ láti fi àwọn irinṣẹ́ gbé e nítorí pé ó máa ń fọ́ wẹ́wẹ́ níkèékèé, ó sì máa ń sọ ojú àwọn irinṣẹ́ dúpú kánkán.[21]

Ní orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì (UK), kò sí ìkálọ́wọ́kò kankan fún ọjà àti mímọ pákó rẹ̀ lẹ́rọ. Ìpalára kan ṣoṣo tí a mọ̀ tí eruku ìrókò ń fà ni àrùn ikọ́-fèé (asthma), àrùn awọ ara (dermatitis) àti wíwú ara.[22]

Ìgbàgbọ́ nínú Àṣà

Igi yìí jẹ́ ohun ẹ̀rù nínú àwọn àṣà kan níbi tí ó ti ṣẹ̀wá, fún ìdí èyí wọ́n máa ń sá fún un tàbí bọ̀wọ̀ fún un pẹ̀lú ẹbọ.[23] Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé igi náà ní ẹ̀mí/àlùjọ̀nnú kan nínú (Olúwéré), àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fojú kòójú rí 'ọkùnrin-Ìrókò' yóò di wèrè, yóò sì tètè kú.[24] Gẹ́gẹ́ bí àṣà Yorùbá, ọkùnrin yíówù tí ó bá gé igi ìrókò lulẹ̀ ń pe oríburúkú kíkàn bá ara rẹ̀ àti gbogbo ìdílé rẹ̀,[24] bótilẹ̀jẹ́pé tí wọ́n bá níláti gé igi náà, wọ́n lè ṣe àdúrà lẹ́yìn rẹ̀ láti dáàbò bo ara wọn.[25]

Wọ́n tún sọ pé wọ́n lè gbọ́ ohùn ẹ̀mí Ìrókò nínú àwọn ilé tí wọ́n fi pákó ìrókò kọ́, nítorí pé ẹ̀mí Ìrókò ti há sínú pákó náà.[24]Nàìjíríà, pákó ìrókò máa ń kù díẹ̀ káàtó nítorí ipò tí ilẹ̀ wà àti ìbàjẹ́ gbòǹgbò (root-rot).[26][27][28] Àwọn ará Ìwọ̀-oòrùn ayé kan máa ń pe igi náà ní "teak àwọn tálákà" ("poor man's teak").[29]

Àwòrán

Àwọn Ìtọ́kasì

  1. Amadi, Pete (2013-09-01) (in en). Conflicted Destiny: Chronicle of a Natural Born Warrior. FriesenPress. ISBN 978-1-4602-2427-4. https://books.google.com/books?id=ezvpAwAAQBAJ. 
  2. D.A. Ofori; M.D. Swaine; C. Leifert; J.R. Cobbinah; A.H. Price (December 2001), "Population genetic structure of Milicia species characterised by using RAPD and nucleotide sequencing L.", Genetic Resources and Crop Evolution, 48 (6): 637–647, Bibcode:2001GRCEv..48..637O, doi:10.1023/A:1013805807957  Unknown parameter |s2cid= ignored (help)
  3. Burkhardt, Lotte (2018). "Verzeichnis eponymischer Pflanzennamen - Erweiterte Edition. Index of Eponymic Plant Names - Extended Edition. Index de Noms éponymiques des Plantes - Édition augmentée" (in German). Verzeichnis eponymischer Pflanzennamen – Erweiterte Edition. Berlin: Botanic Garden and Botanical Museum, Freie Universität Berlin. doi:10.3372/epolist2018. ISBN 978-3-946292-26-5. 
  4. "Milicia Sim | Plants of the World Online | Kew Science". Plants of the World Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 26 October 2021. 
  5. Oduyoye, Modupe (2015-09-29) (in en). The Sons of the Gods and the Daughters of Men: An Afro-Asiatic Interpretation of Genesis 1-11. Wipf and Stock Publishers. ISBN 978-1-4982-3582-2. https://books.google.com/books?id=6HmoCgAAQBAJ. 
  6. Onunwa, Udobata R. (2010-06-27) (in en). A Handbook of African Religion and Culture. Dorrance Publishing. ISBN 978-1-4349-5396-4. https://books.google.com/books?id=LPqZQYiF4jEC. 
  7. Stephen (2023-06-14). "Iroko Wood Is African Teak Lumber 2023" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-06-20. 
  8. Thompson, Robert Farris (26 May 2010) (in en). Flash of the Spirit: African & Afro-American Art & Philosophy. Knopf Doubleday Publishing Group. p. 167. ISBN 978-0-307-87433-7. https://books.google.com/books?id=DzOIY4iHSjAC&dq=iroko+loko.&pg=PA167. Retrieved 23 September 2024. 
  9. Wekker, Gloria; Wekker, Gloria (2006). The politics of passion: women's sexual culture in the Afro-Surinamese diaspora. Between men--between women. New York: Columbia University Press. ISBN 978-0-231-13162-9. OCLC ocm61758062. https://www.worldcat.org/title/ocm61758062. 
  10. Wooding, Charles J. (1981). Evolving culture: a cross-cultural study of Suriname, West Africa, and the Caribbean. Washington, D.C: University Press of America. ISBN 978-0-8191-1378-8. 
  11. Blench, Roger (2006). Archaeology, language, and the African past. Altamira Press. ISBN 978-0-7591-0465-5. 
  12. Quattrocchi, Umberto (3 February 2023) (in en). CRC World Dictionary of Plant Nmaes: Common Names, Scientific Names, Eponyms, Synonyms, and Etymology. CRC Press. p. 1692. ISBN 978-1-000-89773-9. https://books.google.com/books?id=dh2rEAAAQBAJ&dq=iroko+loko.&pg=PA1692. Retrieved 23 September 2024. 
  13. Àdàkọ:Britannica
  14. Àdàkọ:ITIS
  15. Àdàkọ:Cite iucn
  16. Daïnou, K.; Mahy, G.; Duminil, J.; Dick, C. W.; Doucet, J-L; Donkpégan, A S L.; Pluijgers, M.; Sinsin, B. et al. (2014). "Speciation slowing down in widespread and long-living tree taxa: Insights from the tropical timber tree genus Milicia (Moraceae)". Heredity 113 (1): 74–85. Bibcode 2014Hered.113...74D. doi:10.1038/hdy.2014.5. PMC 4815650. PMID 24549110. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=4815650. 
  17. "Wood Species Database: Iroko". Wood Species Database. Timber Research And Development Association (TRADA). Archived from the original on 22 January 2022. Retrieved 21 August 2022.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  18. "La txalaparta, el sonido ancestral de Euskadi por Pol Ducable Rogés". CANCIONEROS.COM. Retrieved 2016-03-04. 
  19. Elleh, Nnamdi (2002-01-01) (in en). Architecture and Power in Africa. Greenwood Publishing Group. ISBN 978-0-275-97679-8. https://books.google.com/books?id=aKoKHmuexywC. 
  20. Kurjatko, Stanislav; Kúdela, Jozef; Lagaňa, Rastislav (2006-01-01) (in en). Wood Structure and Properties '06. Arbora Publishers. ISBN 978-80-968868-4-5. https://books.google.com/books?id=VfuWr1KxrGYC. 
  21. Westin, Mike (2013-04-12) (in en). Upgrading Your Boat's Interior. A&C Black. ISBN 978-1-4081-5909-5. https://books.google.com/books?id=HikdloJ3Z2gC. 
  22. "HSE Toxic Woods Information Sheet" (PDF). Health and Safety Executive. Archived from the original (PDF) on 17 August 2021. Retrieved 15 October 2012. 
  23. Twilight Tales3. CUP Archive. 1953. p. 26. https://books.google.com/books?id=zHw9AAAAIAAJ&pg=PA26. Retrieved 2 April 2011. 
  24. 24.0 24.1 24.2 Ogumefu, M. I. (1929). Yoruba legends. Forgotten Books. p. 10. ISBN 978-1-60506-017-0. https://books.google.com/books?id=c2nt2Vui0qEC&pg=PA10. 
  25. (in en) The Church Missionary Juvenile Instructor. Seeley, Jackson, & Halliday. 1880-01-01. https://archive.org/details/churchmissionar01socigoog. 
  26. (in en) Bulletin of the Imperial Institute. The Institute. 1914-01-01. p. 366. https://books.google.com/books?id=AOsiAQAAIAAJ. 
  27. Commons, Great Britain Parliament House of (1914-01-01) (in en). House of Commons Papers. H.M. Stationery Office. https://books.google.com/books?id=yeoLAQAAIAAJ. 
  28. (in en) Documentation and Information: Ecology: Catalogue of Documents and Publications on MAB in Africa. UNESCO's Regional Office. 1990-01-01. https://books.google.com/books?id=zhsoAQAAMAAJ. 
  29. Hamon, Lindsay (2012-11-07) (in en). When God Takes Over: Stories of hope on the streets. AuthorHouse. ISBN 978-1-4772-3884-4. https://books.google.com/books?id=OblmwE2bFswC. 

Àwọn Ìjápọ̀ Ìta

Àdàkọ:Wikispecies

Content Disclaimer

Informasi ini disarikan dari Wikipedia dan disajikan kembali untuk tujuan edukasi. Konten tersedia di bawah lisensi CC BY-SA 3.0. Kami tidak bertanggung jawab atas ketidakakuratan data yang bersumber dari kontribusi publik tersebut.

  1. The information displayed on this website is sourced in part or in whole from Wikipedia and has been adapted for the purpose of restating it. We strive to provide accurate and relevant information, however:
  2. There is no guarantee of absolute accuracy. Wikipedia is an open, collaborative project that can be edited by anyone, so information is subject to change.
  3. It is not intended to constitute professional advice. The content displayed is for informational and educational purposes only. For important decisions (e.g., medical, legal, or financial), please consult a professional.
  4. Content copyright. Wikipedia is licensed under the Creative Commons Attribution-ShareAlike License (CC BY-SA). This means that content may be reused with appropriate attribution and shared under a similar license.
  5. Responsible use. Any risk arising from the use of information from this website is entirely the responsibility of the user.