Kizz Daniel

Kizz Daniel
A portrait of Kizz Daniel
A portrait of Kizz Daniel
Background information
Orúkọ àbísọOluwatobiloba Daniel Anidugbe
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíiVado
Ọjọ́ìbíOgun State, Nigeria
Irú orin
  • Afrobeats
  • Pop music
  • Pop
  • Contemporary R&B
Occupation(s)
  • Singer
  • Songwriter
  • Entertainer
Years active2014-Present
Labels
Associated acts

Oluwatobiloba Daniel Anidugbe, tí àwọn ènìyàn tún mọ̀ sí orúkọ ìtàgé rẹ̀ Kizz Daniel, jẹ́ olórin àti a-kọ-orin ti ile nijiria Ó gbajúgbajà fún àwọn orin rẹ̀ "Woju" ati "Yeba". Orúkọ ìtàgé Kiss Daniel ni ó ń jẹ́ tẹ́lẹ̀ kí ó tó yí i dà ní oṣù karùn-ún, ọdún 2018. Ó bọwọ́lùwe àdéhùn iṣẹ́ pẹ̀lú G-Worldwide Entertainment ní ọdún 2013, ṣùgbọ́n ó fi ilé-iṣẹ́ orin náà sílẹ̀ lẹ́yìn ìjà lórí àdéhùn tí kì í ṣe gbòńkẹ́lẹ́ àti ìgbẹ́jọ́ nílé ẹjọ́. Ó dá ilé-iṣẹ́ orin Fly Boy Inc record label sílẹ̀ ní oṣù kọkànlá, ọdún 2017.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbésí-ayé

Wọ́n bí Kizz Daniel gẹ́gẹ́ bí i Olúwatóbilọ́ba Daniel Anidugbe ní Abẹ́òkúta , Ìpínlẹ̀ Ògùn , Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọ ìjọba ìbílẹ̀ Abeokuta North.

Ẹ̀kọ́

Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ girama Abeokuta Grammar School, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní Federal University of Agriculture, Abeokuta, ní ọdún 2013, pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí ní Water Resources Management and Agrometeorology.[1] Ní ìgbà tí ó ṣì wà ní Yunifásítì, ó pinnu láti máa lé iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ rẹ̀ papọ̀. [2]

Ìgbé ayé rẹ̀

Ní ọjọ́ kìíní, oṣù karùn-ún, ọdún 2021, ó bí àwọn ìbẹẹ̀ta , Jamal, Jalil àti Jelani, pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀ .[3] Kizz sọ lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ bí ó ṣe pàdánù ọ̀kan nínú àwọn ìbẹẹ̀ta rẹ̀, Jamal, ní ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn ọjọ́ tí ó bí wọn bí ó ṣe ra ilé oníyàrá méjì kọ̀ọ̀kan fún Jalil àti Jelani.[4][5]

Iṣẹ́

Ní oṣù karùn-ún, ọdún 2015, Kizz Daniel láfarabara fi orin kẹta léde tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní, “Laye,” ní ọjọ́ tí ó jẹ́ ọjọ́ ìbí rẹ̀, pẹ̀lú fọ́nrán tí AJE FILMS darí, tí wọ́n yà ní oríṣìíríṣìí ibi ní ìlà-oòrùn Áfíríkà lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí orin náà jáde.

Daniel fi àwo orin rẹ̀ kìíní tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní New Era léde ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù karùn-ún, ọdún, 2016. Lẹ́yìn tí ó fi ilé iṣẹ́ orin tí ó ń bá ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, G-WorldWide, ó lọ dá tirẹ̀ sílẹ̀ FLYBOY I.N.C. tí ó sì gba àwọn olórin tuntun méjì wọlé láìpẹ́ yìí, Demmie Vee àti Philkeyz. Lẹ́yìn èyí ni Kizz Daniel kọ nínú orin Demmie Vee single tí wọ́n pè ní "You Go Wait?".[6] 2018 jẹ́ ọdún tí ó da fún olórin tí ó kọ WOJU, ó pe Wizkid sí orin tí ó gbalégbako "FOR YOU"[7] àti Davido sí orin mìíràn "One Ticket" tí ó gún òkè lorí àtẹ láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún tí wọ́n fi léde. Ní ọjọ́ ọgbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2018, Kizz Daniel fi àwo-orin rẹ̀ kejì léde, èyí tí ó jẹ́ èkíní rẹ̀ lábẹ́ ilé-iṣẹ́ orin FlyBoy Inc tí wọ́n pe àkọ́lé rẹ̀ ní "No Bad Songz". Àwo-orin náà ní orin ogún nínú pẹ̀lú èyí tí ó fi fi léde tẹ́lẹ̀, One Ticket, tí ó kọ pẹ̀lú Davido. Àwọn olórin mìíràn tí ó kọrin pẹ̀lú nínú Àwo-orin náà ni Nasty C, Diamond Platiumz, Philkeyz, Demmie Vee, Dj Xclusive, Wretch 32, Diplo àti Sarkodie. Àwo-orin yìí gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ì-gbóríyìn-fún lọ́dọ̀ àwọn olólùfẹ́ orin, ó gba ipò 55 ní orí US iTunes Chart ó sì gba ipò kìíní lórí àtẹ̀ àwo-orin lágbàáyé láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún tí wọ́n fi léde. Ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹfà, ọdún, ó fi àwo-orin rẹ̀ kẹta 'King of Love'[8][9]léde

Ní 2017, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ni wọ́n rò pé ó máa pàrọ̀ iṣẹ́ sí iṣẹ́ adẹ́rìn-ín-pòṣónú nítorí pé ó ń fi àwọn fọ́nrán apanilẹ́rìn-ín léde. Ṣùgbọ́n ṣá, ó sọ pé òun ò ní èrò láti pàrọ̀ iṣẹ́ sí iṣẹ́ adẹ́rìn-ín-pòṣónú nítorí iṣẹ́ orin gan-an ni ẹ̀bùn òun. [10]

Ìjà ilé-iṣẹ́ orin àti orúkọ yíyídà.

Ní oṣù kọkànlá 2017, Kizz Daniel kéde ìpínyà rẹ̀ kúrò lábẹ́ ilé-iṣẹ́ orin, G-Worldwide, ó sì dá ilé-iṣẹ́ orin tirẹ̀ sílẹ̀ tí ó pe ní FLYBOY I.N.C.[11] Àwọn ilé-iṣẹ́ orin ti tẹ́lẹ̀ gbé e lọ ilé-ẹjọ́ ṣùgbọ́n kò jẹ̀bi ọ̀kankan nínú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.[12] [13]

Ní oṣù karùn-ún 2018, Kizz Daniel kéde pé òun ti yí orúkọ ìtàgé òun kúrò láti Kiss Daniel sí Kizz Daniel, orúkọ èyí tí ó farahàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní orí àwọn ẹ̀rọ ìbánidọ̀ọ̀rẹ́ rẹ̀. Spotify tuntun àti Apple Music accounts di ṣíṣí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pẹ̀lú orúkọ Kizz Daniel, àti àwọn orin rẹ̀ tuntun.[14][15]

Ní oṣù kẹfà 2018, ilé-iṣẹ́ orin ti tẹ́lẹ̀ tí Kizz Daniel wà lábẹ́ wọn, G-Worldwide gbìyànjú láti ní àṣẹ sí orúkọ “Kizz Daniel”, wọ́n sì tún gba olórin yìí níyànjú láti dẹ́kun lílo orúkọ yìí Àbí kí ó fojú winá òfin nínú àtẹ̀jáde ìròyìn tí wọ́n fi ṣọwọ́ sí àwọn ilé ìròyìn. Ní oṣù kẹwàá 2018, Daniel fèsì sí ìwé ìpẹ̀jọ́ àti ọ̀rọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ G-Worldwide láti ẹnu agbẹjẹ́rò tirẹ̀.[16]

Discography

Àtòjọ orin rẹ̀

Àwo-orin/EP

  • Nwe Era (2016)
  • No Bad Songz (2018)[17]
  • King of Love (2020)[18]
  • Barnabas (2021)[19]

Altòjọ àwọn amì-èyẹ tó ti gbà

Year Event Prize Result Ref
2015 The Headies Yàán [20]
Nigeria Entertainment Award Gbàá [21]
City People Entertainment Yàán [22]
Yàán
2016 MTV Africa Music Award Yàán [23]
Nigeria Entertainment Award Gbàá [24]
Gbàá
City People Music Award Gbàá [25]
Yàán [26]
The Headies Gbàá [27][28]
Gbàá
Yàán
Gbàá
2017 The Future Awards Africa Yàán [29]
Nigeria Entertainment Award Yàán
2018 The Headies style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé [30]
style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé
style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé
style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé

Àwọn ìtọ́kasí

  1. "5 interesting facts about the singer". www.pulse.ng. 2017-12-06. Archived from the original on 2019-05-07. Retrieved 2019-05-07. 
  2. Akan, Joey. "Kiss Daniel: 10 things you don"t know about "Woju" singer". Archived from the original on 2018-07-03. https://web.archive.org/web/20180703162914/http://www.pulse.ng/entertainment/music/kiss-daniel-10-things-you-dont-know-about-woju-singer-id3507573.html. 
  3. Omotayo (2021-05-01). "Nigerian singer, Kizz Daniel welcomes a set of twins on his birthday". FreshPopMusic (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-07-24. Retrieved 2021-07-24. 
  4. Omotayo (2021-07-15). "Kizz Daniel reveals how he lost one of his triplets, buys penthouses for Jalil & Jelani". FreshPopMusic (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-07-24. Retrieved 2021-07-24. 
  5. Emmanuel (2021-07-16). "One Of The Triplets Of Kizz Daniel Is Dead, He Confirms" (in en). Archived from the original on 2021-07-27. https://web.archive.org/web/20210727074950/https://candytv.ng/one-of-the-triplets-of-kizz-daniel-is-died-he-confirms/. 
  6. "Demmie Vee ft. Kizz Daniel – You Go Wait?". https://www.mp3bullet.ng/demmie-vee-ft-kizz-daniel-you-go-wait-mp3. 
  7. "Kizz Daniel ft Wizkid - For You". https://www.mp3bullet.ng/kizz-daniel-x-wizkid-for-you-prod-philkeyz-music. 
  8. Alake, Motolani (June 26, 2020). "Kizz Daniel releases new album, 'King of Love'". Pulse Ng. Archived from the original on July 5, 2020. Retrieved July 4, 2020. 
  9. Omotayo (2020-06-04). "Kizz Daniel's King of Love album is dropping June 25 - See Tracklist". FreshPopMusic (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-07-24. Retrieved 2021-07-24. 
  10. "My comedy skits are strategic –Kiss Daniel". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 15 October 2017. Retrieved 2021-02-26. 
  11. "Kiss Daniel Leaves G-Worldwide Label - PM NEWS Nigeria". PM NEWS Nigeria. 2017-11-13. https://www.pmnewsnigeria.com/2017/11/13/kiss-daniel-leaves-g-worldwide-label/. 
  12. "Breaking News & Top Stories | Pulse Nigeria".  /entertainment/music/kiss-daniel-g-worldwide-full-story-id7707718.html
  13. "G-Worldwide drags Kiss Daniel to court". Punch Newspapers. http://www.punchng.com/g-worldwide-drags-kiss-daniel-to-court/. 
  14. "Nigerian musician, Kiss Daniel changes stage name - Daily Post Nigeria". Daily Post Nigeria. 2018-05-22. http://dailypost.ng/2018/05/22/nigerian-musician-kiss-daniel-changes-stage-name/. 
  15. "Kiss Daniel changes name to Kizz Daniel - BellaNaija". www.bellanaija.com. 22 May 2018. Retrieved 2018-07-03. 
  16. Uche, Prinx (October 27, 2019). "Kizz Daniel Fires Back At G-Worldwide Record Label". Luvmp. Archived from the original on September 24, 2021. Retrieved April 30, 2022. 
  17. "Kizz Daniel - No Bad Songz Album - TrendyBeatz.com". Trendybeatz.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 
  18. "DOWNLOAD Kizz Daniel set to drop new album, 'King of Love' tomorrow, releases tracklist". Yahiphop.com. 2020-06-24. Archived from the original on 2020-06-25. Retrieved 2020-06-25. 
  19. "Kizz Daniel drops new EP "Barnabas" - P.M. News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-21. 
  20. "Breaking: Wizkid, Olamide, Praiz, others nominated for #TheHeadies2015!". Vanguard News. 2015-09-30. https://www.vanguardngr.com/2015/09/breaking-wizkid-olamide-praiz-others-nominated-for-theheadies2015/. 
  21. "The Nigeria Entertainment Awards Announce 2015 Nominees". OkayAfrica. 2015-06-15. http://www.okayafrica.com/nigeria-entertainment-awards-nominees-2015/. 
  22. "City People Awards 2015 Nominees List". TooXclusive. 2015-07-13. Archived from the original on 2018-07-03. https://web.archive.org/web/20180703220212/http://tooxclusive.com/news/city-people-awards-2015-nominees-list/90246.html. 
  23. "Here's the Full List of Nominees at the 2016 MTV Africa Music Awards in Johannesburg". OkayAfrica. 2016-10-22. http://www.okayafrica.com/mtv-africa-music-awards-2016-nominees-mtvmama2016/. 
  24. Solanke, Abiola. "NEA 2016: Adekunle Gold, Olamide, Kiss Daniel, others win big". Archived from the original on 2018-07-03. https://web.archive.org/web/20180703162917/http://www.pulse.ng/buzz/nea-2016-adekunle-gold-olamide-kiss-daniel-others-win-big-id5460429.html. 
  25. "Full List Of Winners at 2016 City People Entertainment Awards - Nigerian Entertainment Today". Nigerian Entertainment Today. 2016-07-26. http://thenet.ng/full-list-of-winners-at-2016-city-people-entertainment-awards/. 
  26. Solanke, Abiola. "City People Entertainment Awards 2016: Olamide, Falz, Phyno, Tiwa Savage lead nomination pack". Archived from the original on 2018-07-03. https://web.archive.org/web/20180703220338/http://www.pulse.ng/buzz/city-people-entertainment-awards-2016-olamide-falz-phyno-tiwa-savage-lead-nomination-pack-id5233745.html. 
  27. "Full list of Headies 2016 winners - Vanguard News". Vanguard News. 2016-12-23. https://www.vanguardngr.com/2016/12/full-list-headies-2016-winners/. 
  28. "The Headies Awards 2016: Complete list of Nominees - INFORMATION NIGERIA". INFORMATION NIGERIA. 2016-11-09. http://www.informationng.com/2016/11/headies-awards-2016-complete-list-nominees.html. 
  29. "The Future Awards Africa 2017 Nominees Profiles - The Future Awards Africa". The Future Awards Africa. 2017-11-24. http://thefutureafrica.com/awards/future-awards-africa-2017-nominees-profiles/. 
  30. Ohunyon, Ehis. "The nominees list for the 2018 Headies is out!". Archived from the original on 2018-07-11. https://web.archive.org/web/20180711225320/https://www.pulse.ng/entertainment/music/headies-2018-nominees-list-id8247089.html. 

Content Disclaimer

Informasi ini disarikan dari Wikipedia dan disajikan kembali untuk tujuan edukasi. Konten tersedia di bawah lisensi CC BY-SA 3.0. Kami tidak bertanggung jawab atas ketidakakuratan data yang bersumber dari kontribusi publik tersebut.

  1. The information displayed on this website is sourced in part or in whole from Wikipedia and has been adapted for the purpose of restating it. We strive to provide accurate and relevant information, however:
  2. There is no guarantee of absolute accuracy. Wikipedia is an open, collaborative project that can be edited by anyone, so information is subject to change.
  3. It is not intended to constitute professional advice. The content displayed is for informational and educational purposes only. For important decisions (e.g., medical, legal, or financial), please consult a professional.
  4. Content copyright. Wikipedia is licensed under the Creative Commons Attribution-ShareAlike License (CC BY-SA). This means that content may be reused with appropriate attribution and shared under a similar license.
  5. Responsible use. Any risk arising from the use of information from this website is entirely the responsibility of the user.