Oladele Awobuluyi

Oladele Awobuluyi
Ìbí17 Oṣù Keje 1937 (1937-07-17) (ọmọ ọdún 89)
Okeagbe, Ondo State, Nigeria
PápáÌmọ̀ ẹ̀dá-èdè, Ẹ̀dá-èdè ilẹ̀ Áfíríkà, Ẹ̀dá-èdè Yorùbá
Ilé-ẹ̀kọ́Michigan State University
Lehman College
Yunifásítì ìlú Èkó
Yunifásítì ìlú Ilorin
Adekunle Ajasin University
Ó gbajúmọ̀ fúnYoruba linguistics, African linguistics, syntax, language policy
Àwọn ẹ̀bùn àyẹ́síFellow, Nigerian Academy of Letters

Ọládélé Awóbùlúyì (tí a bí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù keje, ọdún 1937 tí ó papòdà ní ọjọ́ kẹfà, oṣù kẹjọ, ọdún 2026) jẹ́ onímọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè, ọ̀jọ̀gbọ́n, àti òǹkọ̀wé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. A bí i ní Òkèagbe, ní Àríwá ìwọ̀-oòrùn Àkókó, ni ìpínlẹ̀ Òndó, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà .[1] Agbègbè iṣẹ́ ìwádìí Awóbùlúyì dá lórí èdè ilẹ̀ Áfíríkà, pàápàá jùlọ èdè Yorùbá, àti èdè Kanuri àti Edo.[2] Awóbùlúyì dá ẹ̀ka ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ Ẹ̀dá-èdè àti àwọn Èdè Nàìjíríà sílẹ̀ ní Yunifásítì ìlú Ìlọrin ní ọdún 1976, ó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olórí àkọ́kọ́ ní ẹ̀ka náà láti ọdún 1979 títí di oṣù kẹsàn-án, ọdún 1984. [3] [4] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Nigerian Academy of Letters nígbà ayé rẹ̀.[5]

Ẹ̀kọ́ àti ìkọ́ni

Awóbùlúyì gba oyè àkọ́kọ́ (Bá) nínú ẹ̀kọ́ Classics ní Yunifásítì Colorado Boulder ní ọdún 1961, oyè kejì (MA) nínú èdè Látìnì láti Yunifásítì Kòlúmbíà ní ọdún 1962, oyè kejì (MA) nínú ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè láti Yunifásítì Kòlúmbíà ní ọdún 1964, àti oyè ọ̀mọ̀wé (PhD) nínú ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè láti Yunifásítì Kòlúmbíà ní ọdún 1967. [1] Awóbùlúyì ti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Michigan State University, CUNY, Yunifásítì ìlú Èkó, Yunifásítì ìlú Ilorin, àti Yunifásítì Adékúnlé Ajásin.[1]

Àwọn àṣàyàn àtẹ̀jáde

Àwọn ìwé

  • Essentials of Yoruba Grammar
  • Yoruba Metalanguage: a Glossary of English-Yoruba Technical Terms in Language, Literature and Methodology
  • Studies in the syntax of the standard Yoruba verb by Oladele Awobuluyi
  • The New National Policy on Education in Linguistic Perspective
  • Ìléwó ìkòwé Yorùbá òde-òní
  • Peace Corps Yoruba Course
  • Studies in the Syntax of the Standard Yoruba Verb
  • Yorùbá kò gbọdọ̀ kú
  • Linguistics and Nation Building: the Prof. Emeritus Ayọ Bamgbose Personality Lecture

Àwọn àpilẹ̀kọ

  • "On the Reality of Vowel Coalescence in Yoruba", Studies in African Linguistics, December 1985, Vol.9(Dec), pp. 11–14
  • "Issues in the Syntax of Standard Yoruba Focus Constructions", The Journal of West African Languages, Nov 1, 1992, Vol.22(2), p. 69
  • "Towards a Typology of Coalescence", The Journal of West African Languages, November 1987, Vol.17(2), pp. 5–22
  • "On 'The Subject Concord Prefix', in Yoruba", Studies in African Linguistics, Dec 1, 1975, Vol.6(3), p. 215
  • "The Modifying Serial Construction: a Critique", Studies in African Linguistics, Mar 1, 1973, Vol.4(1), p. 87
  • "On the Status of Prepositions", The Journal of West African Languages, Jul 1, 1971, Vol.8(2), p. 101
  • "'High-Tone-Junction-Contracting Verbs' in Yoruba", The Journal of West African Languages, Jan 1, 1970, Vol.7(1), p. 29
  • "The Particle If in Yoruba", The Journal of West African Languages, Jul 1, 1969, Vol.6(2), p. 67

Ìfisọrí

  • Issues in Contemporary African Linguistics: a Festschrift for Ọladele Awobuluyi
  • New Findings in the Study of Nigerian Languages and Literatures: a Festschrift in Honour of Oladele Awobuluyi
  • Current Research in African Linguistics: Papers in Honor of Ọladele Awobuluyi

Nípa ikú

Ọ̀jọ̀gbọ́n Awóbùlúyì papòdà ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹjọ, ọdún 2026 ní ẹni àádọ́rùn-ún ọdún.[6] Lẹ́yìn ìgbà tí ọ̀jọ̀gbọ́n Awóbùlúyì dá gbére fáyé, onírúurú àwọn ìjọ, ẹ̀ka, àti àwọn abánikẹ́dùn ni wọ́n kàn sí ìdílé olóògbé láti bá wọn kẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbóríyìn fún àwọn iṣẹ́ takuntakun tí olóògbé gbáyé ṣe lórí ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè Yorùbá, ìmọ̀ nípa èdè ilẹ̀ Áfíríkà, àti àwọn ẹ̀kọ́ ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Adékúnlé Ajásin, níbi tí wọ́n ti jẹ oyé Gíwa fìdíẹẹ́ láàárín ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kẹfà, ọdún 2009 sí ọjọ́ kẹta, oṣù kìíní, ọdún 2010, náà sọ nípa ipa ribiribi tí olóògbé kó lórí ilé-ẹ̀kọ́ náà.[7]

Àwọn ìtọ́kasí

  1. 1.0 1.1 1.2 (in en) Current Research in African Linguistics: Papers in Honor of Qladele Awobuluyi. Cambridge Scholars Publishing. 2015-09-01. ISBN 9781443881425. https://books.google.com/books?id=5HrWCgAAQBAJ&q=Adekunle+Ajasin+University,+Akungba+Akoko+%22awobuluyi%22+2009&pg=PR11. 
  2. Ndimele, Ozo-mekuri; Yuka, Lendzemo Constatine (2016-07-25) (in en). Issues in Contemporary African Linguistics: A Festschrift for Oladele Awobuluyi. M & J Grand Orbit Communications. ISBN 9789785412789. https://books.google.com/books?id=Eq7HDAAAQBAJ&q=Oladele+Awobuluyi+&pg=PR6. 
  3. https://www.unilorin.edu.ng/index.php/registry/373-faculties/arts/5727-department-of-linguistics-and-nigerian-languages
  4. https://web.archive.org/web/20181222082014/http://www.unilorin.edu.ng/index.php/373-faculties/arts/5727-department-of-linguistics-and-nigerian-languages
  5. https://web.archive.org/web/20180825235425/http://nal.org.ng/fellows
  6. "Renowned Linguist, Professor Emeritus Oladele Awobuluyi dead". News Wings. 6 August 2026. https://newswings.com.ng/renowned-linguist-professor-emeritus-oladele-awobuluyi-dead/. 
  7. "Past Vice Chancellors". Adekunle Ajasin University. Retrieved 8 August 2026. 

Content Disclaimer

Informasi ini disarikan dari Wikipedia dan disajikan kembali untuk tujuan edukasi. Konten tersedia di bawah lisensi CC BY-SA 3.0. Kami tidak bertanggung jawab atas ketidakakuratan data yang bersumber dari kontribusi publik tersebut.

  1. The information displayed on this website is sourced in part or in whole from Wikipedia and has been adapted for the purpose of restating it. We strive to provide accurate and relevant information, however:
  2. There is no guarantee of absolute accuracy. Wikipedia is an open, collaborative project that can be edited by anyone, so information is subject to change.
  3. It is not intended to constitute professional advice. The content displayed is for informational and educational purposes only. For important decisions (e.g., medical, legal, or financial), please consult a professional.
  4. Content copyright. Wikipedia is licensed under the Creative Commons Attribution-ShareAlike License (CC BY-SA). This means that content may be reused with appropriate attribution and shared under a similar license.
  5. Responsible use. Any risk arising from the use of information from this website is entirely the responsibility of the user.