Phyna

Phyna
Ọjọ́ìbíPhyna Ijeoma Josephina Otabor
2 Oṣù Kẹfà 1997 (1997-06-02) (ọmọ ọdún 29)
Edo State, Nigeria
Orúkọ mírànHype priestess of Nigeria
Gbajúmọ̀ fúnWinner of Big Brother Naija season 7
TelevisionBig Brother Naija
Parents
  • Moses Otabor (father)
  • Gladys Moses Otabor (mother)

Ijeoma Josephina Otabor LL-Q33578 (ibo)-Vivian Amalachukwu-Ijeoma Josephina Otabor.wav Listen (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejì oṣù Kẹfà ọdún 1997), ẹni tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Phyna, jẹ́ òṣèrébìnrin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Òun ló jáwe olúborí fún ètò Big Brother Naija apá keje.[2][3][4][5]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

[6] Ní àsìkò tí ó wà lórí ètò Big Brother, ó sọ ọ́ di mímọ̀ pé òun jẹ́ ọmọ Igbo, bó tilè jẹ́ pé ìlú rè tí ń ṣe Ekpon wà ní Ìpínlẹ̀ Edo. Ó dàgbà sí Auchi, ní Ìpínlẹ̀ Edo, níbi ti ó ti ka ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ti girama rẹ̀.[7] Ó parí ètò ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀ ní Ẹ̀ka Ìmọ̀ Ẹ̀rọ ní Auchi Polytechnic.[8]

Iṣẹ́ rẹ̀

Kí ó tó di pé ó darapọ̀ mọ́ ètò Big Brother Naija, Phyna máa ń ṣiṣẹ́ módẹ́ẹ̀lì, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ lásìkò tó wà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, tí àwọn ilé-isẹ́ módẹ́ẹ̀lì sì gbà á síṣẹ́.[9]

Big Brother Naija

Phyna darapọ̀ mọ́ ètò Big Brother Naija ti apá Keje, gẹ́gẹ́ bí ẹni kẹwàá ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù Keje ọdún 2022.[10][11]

Lásìkò tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ láti kẹ́sẹ̀ ètò náà nílẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù Kẹwàá ọdún 2022, wọ́n kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi akópa tó jáwé olúborí tí ó gba ìbò 40.74%, èyí tí ó fi ju ti Bryann lọ, ìyẹn ẹni tó gba ìbò 26.74%. Àwọn agbátẹrù ètò yìí fún Phyna ní ₦100 000 000 (ọgọ́rùn-ún mílíọ́nù náírà),[12][13] èyí sì sọ ọ́ di obìnrin ẹlẹ́ẹ̀kejì tó máa jáwé olúborí nínú ètò náà, èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí Mercy Eke jáwé olúborí.[14][15][16]

Aṣojú ilé-iṣẹ́

Phyna jẹ́ aṣojú fún àwọn ilé-iṣẹ́ bí i: Firegin, Spedy Herbals, Rixari Skin Secrets, BeUnique Wears, Spedy Weightloss[17]

Àwọn fíìmù rẹ̀

Ti orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán

Ọdún Àkọ́lé Ipa Ọ̀rọ̀
2022 Big Brother Naija 7 Contestant Reality TV Show
2023 Leaving Beauty Mabel Produced by Mike Ezuruonye
2023 Shattered Innocence Theresa Produced by Abdulgafar Ahmad Oluwatoyin
2023 Osato Osato Produced by Charles Uwagbai and Etinosa Idemudia
2023 Ada Omo Daddy Produced by Mercy Aigbe
2024 House of trouble Produced by Mercy Johnson

Àmì-ẹ̀yẹ

Ọdún Ayẹyẹ Ẹ̀bùn Èsì
2022 All Varieties Award People's Choice of The Year Gbàá
2022 Africa Choice Awards Honorary Award of Excellence Gbàá
2023 Trendupp Awards Force of Online Sensation Gbàá
2023 La Mode Awards Celebrity of The Year (Female) Gbàá
2023 Man on Cheq Most Outspoken Female Celebrity Gbàá
2023 Edo State International Film Festival Best Actress In a Movie "Osato" Gbàá

Àwọn ìtọ́kasí

  1. olufemiajasa (2022-10-02). "Breaking: Phyna beats Bryan, emerges winner of BBNaija Level Up season" (in en-GB). Vanguard (Lagos, Nigeria). https://www.vanguardngr.com/2022/10/breaking-phyna-beats-bryan-emerges-winner-of-bbnaija-level-up-season/. 
  2. Alake, Olumide (2022-10-02). "BBNaija 2022 finale: Phyna emerges winner of season 7 edition" (in en). Legit.ng. https://www.legit.ng/entertainment/tv-shows/1495496-bbnaija-2022-finale-phyna-emerges-winner-season-7-bryann-second-runner-up/. 
  3. "Live Show 12 – 2 Oct: Phyna wins BBNaija Level Up! - BBNaija". Big Brother Naija - Live Show 12 – 2 Oct: Phyna wins BBNaija Level Up! - BBNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-02. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  4. Nseyen, Nsikak (2022-10-02). "BREAKING: Phyna emerges winner of BBNaija Season 7" (in en-US). Daily Post (Lagos, Nigeria). https://dailypost.ng/2022/10/02/breaking-phyna-emerges-winner-of-bbnaija-season-7/. 
  5. "BREAKING: Phyna wins BBNaija season 7" (in en-US). The Punch. 2022-10-02. https://punchng.com/breaking-phyna-wins-bbnaija-season-7/. 
  6. Wamangu, Peris (2022-08-06). "BBNaija Phyna's biography: age, state of origin, socials" (in en). Legit.ng. https://www.legit.ng/ask-legit/biographies/1483180-bbnaija-phynas-biography-age-state-origin-socials/. 
  7. "Things to know about BBNS7 winner, Phyna" (in en-US). The Punch. 2022-10-02. https://punchng.com/things-to-know-about-bbns7-winner-phyna/. 
  8. Editor 3 (2022-08-24). "BBNaija: 'I'm a first class graduate of Engineering, no be by big grammar" - Phyna brags following clash with Sheggz" (in en-US). National Accord (Abuja, Nigeria). https://www.nationalaccordnewspaper.com/bbnaija-im-a-first-class-graduate-of-engineering-no-be-by-big-grammar-phyna-brags-following-clash-with-sheggz/. 
  9. Wamangu, Peris (2022-08-06). "BBNaija Phyna's biography: age, state of origin, socials". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2026-05-31. 
  10. David (2022-07-23). "Meet first 12 Big Brother Naija Season 7 "Level Up" Housemates" (in en-us). The Sun (Lagos, Nigeria). https://www.sunnewsonline.com/meet-first-12-big-brother-naija-season-7-level-up-housemates/. 
  11. "Meet first 12 BBNaija "Level Up" housemates: What to expect - P.M. News" (in en-US). P.M. News (Lagos, Nigeria). https://pmnewsnigeria.com/2022/07/23/meet-first-12-bbnaija-level-up-housemates-what-to-expect/. 
  12. Owolawi, Taiwo (2022-10-02). ""Who deyyyyy": Nigerians celebrate Phyna's BBNaija Level Up win" (in en). Legit.ng. https://www.legit.ng/entertainment/tv-shows/1495512-deyyy-nigerians-gaga-social-media-phyna-emerges-winner-bbnaija-level-season/. 
  13. Alake, Olumide (2022-10-02). "BBNaija 2022 finale: Phyna emerges winner of season 7 edition" (in en). Legit.ng. https://www.legit.ng/entertainment/tv-shows/1495496-bbnaija-2022-finale-phyna-emerges-winner-season-7-bryann-runner-up/. 
  14. "Phyna Wins 2022 BBNaija, Pockets N100m Grand Prize | Channels Television". www.channelstv.com. Retrieved 2022-10-02. 
  15. "Phyna Emerges Second Female Big Brother Naija Winner After Mercy Eke – Independent Newspaper Nigeria". Independent (Lagos, Nigeria). https://independent.ng/phyna-emerges-second-female-big-brother-naija-winner-after-mercy-eke/. 
  16. Madukwe, Bartholomew (2022-10-02). "Whitemoney hails Phyna on emergence as second female BBNaija winner". TheNewsGuru (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-02. 
  17. Donald (2022-07-01). "Phyna BBNaija: ( Josephine Otabor ) Early life ,Dance, School, Net Worth, Photos, University, Biography, Movies, Modelling Agency, YouTube, Boyfriend, TikTok, Makeup, Parents, Height, Wikipedia.". Cloutgist (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-02. 

Content Disclaimer

Informasi ini disarikan dari Wikipedia dan disajikan kembali untuk tujuan edukasi. Konten tersedia di bawah lisensi CC BY-SA 3.0. Kami tidak bertanggung jawab atas ketidakakuratan data yang bersumber dari kontribusi publik tersebut.

  1. The information displayed on this website is sourced in part or in whole from Wikipedia and has been adapted for the purpose of restating it. We strive to provide accurate and relevant information, however:
  2. There is no guarantee of absolute accuracy. Wikipedia is an open, collaborative project that can be edited by anyone, so information is subject to change.
  3. It is not intended to constitute professional advice. The content displayed is for informational and educational purposes only. For important decisions (e.g., medical, legal, or financial), please consult a professional.
  4. Content copyright. Wikipedia is licensed under the Creative Commons Attribution-ShareAlike License (CC BY-SA). This means that content may be reused with appropriate attribution and shared under a similar license.
  5. Responsible use. Any risk arising from the use of information from this website is entirely the responsibility of the user.