The Set Up 2

The Set Up 2
AdaríNaz Onuzo
Olùgbékalẹ̀Inkblot Productions, Film One Entertainment, and Anakle Studios
Òǹkọ̀wéNaz Onuzo
Àwọn òṣèréNancy Isime
Adesua Etomi
Kehinde Bankole
Ilé-iṣẹ́ fíìmùInkblot Productions
OlùpínFilmOne Distributions
Anakle Films
Déètì àgbéjáde
  • 12 Oṣù Kẹjọ 2022 (2022-08-12)
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèEnglish

The Set Up 2 jẹ́ eré oníṣé Ọlọ́tẹlẹ̀múyẹ́ Amárabùmáṣọ tí wọ́n ṣe àgbéjáde rẹ̀ ní orílè-èdè Nàìjíríà ní ọdún un 2022, ó sì jẹ́ apá kejì sí The Set Up, tí wọ́n ṣàgbéjáde ní ọdún 2019. Inkblot Productions, Film One Entertainment àti Anakle Studios ni wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti ṣe àgbéjáde apá kejì eré yìí. Naz Onuzo ni olùdarí eré náà, ẹni yìí ni ó rọ́pòo Niyi Akinmolayan, tí ó darí apá kìn-ín-ní .[1]Àwọn òṣèré akópa nínú eré yìí ni Adesua Etomi, Kehinde Bankole, Nancy Isime, Jim Iyke, Tina Mba, Uzor Arukwe, Kate Henshaw, Blossom Chukwujekwu, Stan Nze, Lota Chukwu àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[2] Wọ́n ṣe àgbéjáde eré yìí ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù kẹ́jọ, ọdún un 2022 .[3]

Ìsọníṣókí

The Set Up 2 jẹ́ apá kejì eré "The Set Up" tí wọ́n ṣàgbéjáde ní ọdún un 2019. Eré náà dá lóri Chike lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tí ìṣẹ̀lẹ̀ eré àkọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, bí ó ṣe ń tiraka láti gba lòtìítọ́ pé òun ti di aṣojú fún àjọ àgbáyé kan. Wọ́n fi ipa mú Chike láti fi gbogbo ohun tí ó ń ṣe sílẹ̀ kí ó sì tọ̀pa ọdaran kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ pè Usi Ìgbà tó di wí pé ọ̀rọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ́jú.[4]

Àwọn Òṣèré Akópa

  • Adesua Etomi kópa gẹ́gẹ́ bíi Chike
  • Kehinde Bankole kópa gẹ́gẹ́ bíi Grace
  • Nancy Isime kópa gẹ́gẹ́ bíi Usi
  • Jim Iyke kópa gẹ́gẹ́ bíi Edem
  • Kate Henshaw kópa gẹ́gẹ́ bíi Teju
  • Tina Mba kópa gẹ́gẹ́ bíi Madam
  • Uzor Arukwe kópa gẹ́gẹ́ bíi Dimeji
  • Blossom Chukwujekwu kópa gẹ́gẹ́ bíi Igwe Mackintosh
  • Stan Nze kópa gẹ́gẹ́ bíi Obiora
  • Lota Chukwu kópa gẹ́gẹ́ bíi Omada
  • Tope Olowoniyan
  • Grace Abah kópa gẹ́gẹ́ bíi Aṣọ́gbà
  • Seun Akindele kópa gẹ́gẹ́ bíi Mayowa Kuku
  • Chris Attoh kópa gẹ́gẹ́ bíi Eugene
  • Onyeama Anthony kópa gẹ́gẹ́ bíi Patron
  • Nsikan Allen kópa gẹ́gẹ́ bíi Omani
  • Tomisin Ayoade kópa gẹ́gẹ́ bíi young Grace
  • Amaju Cedric kópa gẹ́gẹ́ bíi ọkùnrin olówó
  • Bolaji Egbebi kópa gẹ́gẹ́ bíi Ọmọọ̀dọ̀
  • Gbubemi Ejeye kópa gẹ́gẹ́ bíi Nkoyo
  • Kratos Enahoro kópa gẹ́gẹ́ bíi Obadiah

Ìṣàfihàn

Wọ́n ṣe àfihàn àkọ́kọ́ eré yìí "The Set Up 2" ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kéje oṣù Kẹ́jọ ọdún un 2022 ní ìlú Èkó, ní sinimá IMAX Filmhouse tó wà ní agbègbè Lekki ní Èkó. Àwọn òṣèré ọkùnrin àti obìnrin tó kópa nínú eré yìí ni wọ́n péjúpésẹ̀ síbẹ̀ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèré tí wọn ò kópa nínú eré yìí ni wọ́n wá sí ibi àpéjọ yìí àwọn òṣèré bíi, Tobi Bakre, Lala Akindoju, Jemima Osunde, Adunni Ade, Femi Adebayo, Mr Macaroni àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí

Content Disclaimer

Informasi ini disarikan dari Wikipedia dan disajikan kembali untuk tujuan edukasi. Konten tersedia di bawah lisensi CC BY-SA 3.0. Kami tidak bertanggung jawab atas ketidakakuratan data yang bersumber dari kontribusi publik tersebut.

  1. The information displayed on this website is sourced in part or in whole from Wikipedia and has been adapted for the purpose of restating it. We strive to provide accurate and relevant information, however:
  2. There is no guarantee of absolute accuracy. Wikipedia is an open, collaborative project that can be edited by anyone, so information is subject to change.
  3. It is not intended to constitute professional advice. The content displayed is for informational and educational purposes only. For important decisions (e.g., medical, legal, or financial), please consult a professional.
  4. Content copyright. Wikipedia is licensed under the Creative Commons Attribution-ShareAlike License (CC BY-SA). This means that content may be reused with appropriate attribution and shared under a similar license.
  5. Responsible use. Any risk arising from the use of information from this website is entirely the responsibility of the user.