Wizard Chan
Wizard Chan | |
|---|---|
| Orúkọ àbísọ | Fuayefika Maxwell |
| Ọjọ́ìbí | Àsìṣe ìgbéọ̀rọ̀sílẹ̀: Àìdámọ̀ ọ̀rọ̀ "dd". YYYY Port Harcourt, Rivers State, Nigeria |
| Irú orin | |
| Occupation(s) |
|
| Instruments |
|
| Years active | 2020–present |
| Labels | Chan Empire |
Fuayefika Maxwell ( tí wọ́n bí ní 26, June) tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí ‘Wizard Chan’ jẹ́ olórin Afro ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ó ṣe àgbéjáde orin rẹ̀ àkọ́kọ́ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ 'Halo Halo' ní ọdún 2020. Àmọ́, ìgbà tí ó ṣẹ̀ ṣe àgbéjáde orin tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ ‘Earth Song’ ni ó di gbajúmọ̀, ìyẹn ní oṣù December ọdún 2022. Ní ọdún 2023, ó gba àmì-ẹ̀yẹ The Headies àti Galaxy Music Awards.[2]
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
Wọ́n bí Maxwell ní 26 June ní ìlú Okrika, ní Ìpínlẹ̀ Rivers, sínú ìdílé Olóyè & Mrs Fuayefika, gẹ́gẹ́ bíi àbígbẹ̀yìn nínú àwọn ọmọ márùn-ún. Ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Port Harcourt, bẹ́ẹ̀ sì ni ó lo ìgbà èwe rẹ̀ níbẹ̀. Ó gba ẹ̀kọ́ girama láti De World International Secondary School, ní Ìpínlẹ̀ Rivers. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Wisconsin International University College ní Accra, Ghana níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìpolówó ọjà. Ó padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó sì lọ sí Ìpínlẹ̀ Sokoto fún NYSC.[3]
Àtọ̀jọ àwọn orin rẹ̀
Àwọn orin àdákọ
- Halo Halo
- Truth
- Y.O.L.O
- Miss You -- Thousand Voice ft Wizard Chan (2022)
- Earth Song
- Highlife
- Moses ft Boma Nime [4]
- Drumline -- 01FRNCH ft Wizard Chan
- Beast of Our nation -- King Perryy ft Wizard Chan & Tuzi [5]
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ
| Ọdún | Àmì-ẹ̀yẹ | Ìsọ̀rí | Ẹni tí wọ́n yán | Èsì | Ìtọ́ka |
|---|---|---|---|---|---|
| 2023 | The Headies | Best Alternative Song of the year | Earth song | Gbàá | [6] |
| Best Songwriter of the Year | Himself | Wọ́n pèé | [6] | ||
| Galaxy Music Awards | Best Alternative Song of the year | Earth song | Gbàá | [7][8] |
Àwọn ìtọ́kasí
- ↑ "Spotlight Monday – Wizard Chan - The49thStreet" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2023-09-04. Retrieved 2024-01-23.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Rema, Burna Boy, Wizard Chan Top 2023 Headies Awards: Full Winners List". Billboard. 2023-09-04. https://www.billboard.com/music/awards/headies-awards-2023-full-winners-list-rema-burna-boy-1235405814/. Retrieved 2024-01-23.
- ↑ Jayeoba, Deborah (2023-04-11). "Wizard Chan: The Messenger Of The Creator | African Folder" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-01-23.
- ↑ "The Best Afrobeats Songs Right Now - Okayplayer". www.okayafrica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2024-01-23. Retrieved 2024-01-23.
- ↑ BellaNaija.com (2023-06-23). "New Music: King Perryy feat. Wizard Chan & Tuzi – Beast of our Nation" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-01-23.
- ↑ 6.0 6.1 "Headies Award 2023 nominees list: Asake, Burna Boy, Tiwa Savage plus odas wey make di list". BBC News Pidgin. 2023-07-12. Retrieved 2024-01-23.
- ↑ "Winners at The 5th Edition Of The Galaxy Music Awards". Galaxy Music Awards. Archived from the original on 2024-09-17. https://web.archive.org/web/20240917044511/https://galaxymusicawards.com/winners-at-the-5th-edition-of-the-galaxy-music-awards/.
- ↑ "Galaxy Music Awards 2023: Odumodu Blvck, Burna Boy, Omah Lay, Wizard Chan, Flavour dominate nominees' list". Vanguard Newspaper. https://www.vanguardngr.com/2023/11/galaxy-music-awards-2023-odumodu-blvck-burna-boy-omah-lay-flavour-dominate-nominees-list/.
Content Disclaimer
Informasi ini disarikan dari Wikipedia dan disajikan kembali untuk tujuan edukasi. Konten tersedia di bawah lisensi CC BY-SA 3.0. Kami tidak bertanggung jawab atas ketidakakuratan data yang bersumber dari kontribusi publik tersebut.
- The information displayed on this website is sourced in part or in whole from Wikipedia and has been adapted for the purpose of restating it. We strive to provide accurate and relevant information, however:
- There is no guarantee of absolute accuracy. Wikipedia is an open, collaborative project that can be edited by anyone, so information is subject to change.
- It is not intended to constitute professional advice. The content displayed is for informational and educational purposes only. For important decisions (e.g., medical, legal, or financial), please consult a professional.
- Content copyright. Wikipedia is licensed under the Creative Commons Attribution-ShareAlike License (CC BY-SA). This means that content may be reused with appropriate attribution and shared under a similar license.
- Responsible use. Any risk arising from the use of information from this website is entirely the responsibility of the user.